Play Open

ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ YÓÒ MÚ OJÚṢE IṢẸ́ Ọ̀NÀ LỌ́KÚNKÚNDÙN – UMAHI LÓ ṢÈDÁNILÓJÚ NÁÀ FÚN GÓMÌNÀ OYÈBÁNJÍ

Mínísítà fúnṣẹ́ òde, Olùmọ̀ẹ̀rọ Dave Umahi ti gbóríyìn fún Gómìnà Èkìtì, Ọ̀gbẹ́ni Bíọ́dún Oyèbánjí fún ìfarajì rẹ̀ lórí ìpèsè àwọn ohun amáyérọrùn ní ìpínlẹ̀ yí tó sì nfi dáa lójú pé ìjọba àpapọ̀ yóò ṣe kóyákóyá sáwọn ojúṣe ọ̀nà tó n lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn tíjọba àpapọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé fún kóngilá l’Ékìtì.

Àkókò tí Umahi wá ṣe àbẹ̀wò sáwọn ọ̀nà l’Ékìtì pẹ̀lú ìbárìnjáde Gómìnà àtikọ̀ ilé-iṣẹ́ tó n ṣiṣẹ́ ọ̀nà l’Ékìtì ló ṣèdánilójú ọ̀hún.

Ó ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni Gómìnà Oyèbánjí ti n pe àkíyèsí ìjọba àpapọ̀ sáwọn ọ̀nà tíkò dára l’Ékìtì, pàápàá jùlọ àwọn tó jẹ́ tìjọba àpapọ̀ lójúnà átileè mú kọ́rọ̀ ajé àwọn ènìyàn rẹ̀ gbòòrò sí.

Àwọn ọ̀nà tíwọ́n ṣe àbẹ̀wò sí ọ̀hún ni Àkúrẹ́ – Ìkẹ́rẹ́ – Adó oníbejì, ọ̀nà Adó – ABUAD – Ìjàn tí ìjọba àpapọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ fọwọ́sí ṣíṣe rẹ̀.

Nígbà tó wà nbáàwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tóti ṣe àbẹ̀wò sáwọn ọ̀nà náà, Umahi ní èrèdí ìbẹ̀wò ọ̀hún ni láti mọ ipò táwọn ọ̀nà ìjọba àpapọ̀ wà l’Ékìtì, pàápàá jùlọ, ipò tọ́nà Adó sí Ìjan Èkìtì àti ọ̀nà Adó sí Ìkẹ́rẹ́ sí Àkúrẹ́ wà báyíì.

Ó ni,àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ṣe pàtàkì nítorípé wọ́n so ìpínlẹ̀ Èkìtì mọ́ àwọn ìpínlẹ̀ míràn tó yíi ká àti pé ilé-iṣẹ́ rẹ̀ yóò ríi dájú pé àwọn iṣẹ́ ọ̀nà wọ̀nyí yóò parí ní kíákíá.

Posted in ÌRÒYÌN
Previous
All posts
Next

Write a comment

Ministry of
Information

The official Website, Office of Ekiti State Ministry of Information

Contact Us

+234 8160768195

© 2023 EKSG – Ministry of Information . All Rights Reserved.