Play Open

ÌJỌBA ÉKÌTÌ RA ỌGBỌ̀N ỌKỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ÀWỌN OLÙTAJÀ ỌKỌ̀ LẸ́SẸ̀ KÙKÚ LÁTI KOJÚU ÈTÒ ÀBÒ LÉKÌTÌ

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì,Ọ̀gbẹ́ni Oyèbánjí ti ra ọgbọ̀n ọkọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò ọkọ̀ lẹ́sẹ̀kùkú láti gbógun ti àìsetò àbò tó gbòde kan lákókò yìí,tígbésẹ̀ ọ̀hún yóò ró àwọn Amọ̀tẹ́kùn lágbára kíwọ́n leè gbógun ti àwọn ajínigbé ní ìpínlẹ̀ yí.
Oyèbánjí sọ pé,ríra àwọn ọkọ̀ wọ̀nyí látọ̀dọ̀ Oníṣòwò l’Ekìtì fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé ìsèjọba rẹ̀ nṣe àmúsẹ òfin àmúgbòòrò ọrọ̀ ajé tiwantiwa láti leè mú ìdàgbàsókè bá ohun táa leè rí tà lágbègbè wa.
Gómìnà Oyèbánjí, tígbákejì rẹ̀,Arábìnrin Monísádé Afúyẹ́ lọ sojú fún níbi tíwọ́n ti ngba àwọn Ọkọ̀ náà wọlé ṣèlérí péé,ìjọba yóò jà kíkankíkan lòdì sí ohunkóhun tó bá fẹ́ sèdíwọ́ fáwọn Olùdáléiṣẹ́ sílẹ̀ l’Ekiti.

Gómìnà tó bẹnu àtẹ́ lu àwọn oníṣẹ́ẹbi tíwọ́n pa àwọn Ọba Alaye méjì l’Ekìtì àti ìjínigbé àwọn Ọmọ ilé ìwé àtolùkọ́ sọ pé,àwọn ọkọ̀ àmúṣiṣẹ́ wọ̀nyí á ran ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn lọ́wọ́ láti gbogun ti àwọn agbésùnmọ̀mí wọ̀nyìí.
Ó wá ṣèlérí ìgbáradì ìjọba
rẹ̀ láti dojú ogun kọ ohunkóhun tó bá fẹ́ da omi àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ táráàlú ngbádùn rú,Ó fi kún pé,kò léè sí ìdàgbàsókè tó ṣẹ sàn án níbi tétò àbò bá ti mẹ́hẹ.
Gómìnà Oyèbánjí wá sèdánilójú pé,ìjọba rẹ̀ yóò máa ṣe àmúlò àwọn Oníṣòwò àyíká wa,pé iṣẹ́ tíwọ́n bá leè ṣe nìjọba Rẹ̀ kò ní gbé fún àwọn Kọgilá látòkèèrè.

Posted in ÌRÒYÌN
Previous
All posts
Next

Write a comment

Ministry of
Information

The official Website, Office of Ekiti State Ministry of Information

Contact Us

+234 8160768195

© 2023 EKSG – Ministry of Information . All Rights Reserved.