Play Open

ALÁGA ILÉ-IṢẸ́ SUBEB GBÓRÍYÌN FÚN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ FÚN IṢẸ́ TAKUNTAKUN TÍ WỌ́N ṢE LÓRÍ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ ALÁKỌ́BẸ̀RẸ̀ L’ÉKÌTÌ

Alága ilé-iṣẹ́ tó n rísí ètò ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ l’Ékìtì, Ọ̀mọ̀wé Fẹ́mi Akínwùnmí ti gbóríyìn fún àwọn òṣìṣẹ̀ ilé-iṣẹ́ náà fún akitiyan wọn lẹ́nu iṣẹ́, eyí tí ó mú ipele ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ tayọ láti bíi ọdún kan sẹ́yìn l’Ékìtì.

Nígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn ẹ̀ka-ò-jẹ̀ka ilé-iṣẹ́ náà nílù Adó, Ọ̀mọ̀wé Akínwùnmí sọ pé akitiyan àwọn òṣìṣẹ̀ náà ni ó ti kópa nínú àṣeyọrí ilé-iṣẹ́ náà fún ọdún tí wọn n ṣayẹ̀wò rẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀hún.

Lára ètò ọ̀hún ni ṣíṣe àlàyé ibi tí wọ́n báṣẹ́dé láti ọ̀wọ́ àwọn akọ̀wé ilé-ẹ̀kọ́ láti ẹ̀ka ẹ̀kó níjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndínlógún ìpínlẹ̀ yí, láti jẹ́kí àwọn olùdarí àti àwọn akọ̀wé ilé-ẹ̀kọ́ ọ̀hún ṣàlàyé àwọn iṣẹ́ àti ètò tí wọ́n ṣe láàrín oṣù kíní sí oṣù kéjìlá ọdún 2023.

Ọ̀gá SUBEB ọ̀hún gbóríyìn fáwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ní bíwọ́n ṣe n ṣiṣẹ́, ètò ìnàwó àti bí wọ́n ṣe n ṣe àbojútó tó péye sí ilé-ìwé káàkiri.

Ó wá képè àwọn ẹ̀ka-ò-jẹ̀ka ilé-iṣẹ́ náà láti ní àfojúsùn kan èyí tí yóò mú ìpinnu ilé-iṣẹ́ ọ̀hún wá sí ìmúṣẹ ní gbogbo ọ̀nà.

Posted in ÌRÒYÌN
Previous
All posts
Next

Write a comment

Ministry of
Information

The official Website, Office of Ekiti State Ministry of Information

Contact Us

+234 8160768195

© 2023 EKSG – Ministry of Information . All Rights Reserved.