Play Open

KỌMÍṢỌ́NÀ FÚNLÉ IṢẸ́ ÌPÈSÈ NÍNÍ ÀLÙYỌ PÈ FÚN ÀTÌLẸ́YÌN ÀWỌN ỌBA LÓRÍ BÁNKÌ LẸ́SẸ̀ KÙKÚ

Lójúnà àti mú kó rọrùn fáwọn ìlú àti ṣàgọ́dabúlé l’Ékìtì láti máa rówó gbà lóòrèkóòrè, nìjọba ṣe fẹ́ gbé bánkì orí ẹ̀rọ ayélujára kéékèèkéé káàkiri àwọn ìlú àti sàgọ́dabúlé l’Ékìtì kalẹ̀ tí ìjọba sì n képe awon ọba láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ojúṣe tuntun náà láti mú kó kẹ́sẹ járí.

Àkókò tí alábojútó ilé-iṣẹ́ tó n rísí ìpèsè ọrọ̀ àtiṣẹ́ l’Ékìtì, Ọ̀túnba Káyọ̀dé Fáṣaè lọ ṣe ẹnlẹ́ nbẹ̀un sọ́fíìsì àwọn ọba wọ̀nyí l’Ádó ló fun ipè ọ̀hún, ó ní àwọn olórí ìlú wọ̀nyí nípa ribiribi láti kó nímímú bànkì ọlọ́dọni wọ̀nyí kẹ́sẹ járí l’Ékìtì.

Ọ̀túnba Fáṣaè ní ó tó òjìlélúgba ó lé mẹ́wà mílíọ̀nù náírà tí Gómìnà Oyèbánjí ti fọwọ́sí láti mú kójúṣe náà gbérasọ, tí ànfàní ìyáwó yóò wà fáwọn ènìyàn láti bẹ̀rẹ̀ òwò kékèké àti nlá lábẹ́ ilé-iṣẹ́ tó n rísí ìpèsè iṣẹ́ pẹ̀lú ìrànwọ́ owó (ETF).

Ó ní ìjọba yíí ní ìkọ̀nlọ́kàngbọ̀ngbọ̀n fún ìgbé ayéere àtìdàgbàsókè àwọn aráàlú àti pé owó ìyàsọ́tọ̀ fún ìrànwọ́ àwọn oníṣòwò náà ni yóò ní àlésí bénbélé tí kò leè kánni léegun ẹ̀yìn- èyí táa mọ̀ sí (interest.)

Alábojútó ilé-iṣẹ́ tó n rónilágbára láti leè dèèyàn láwùjọ ọ̀hún sọ pé,ilé ìfowópamọ́ tàbí gbowó alábọ́dé náà nígbà tójúṣe rẹ̀ bá kalẹ̀ tán yóò fòpin sí ogun àìrówó ṣòwò láwọn ìgbèríko, yóò tún pèsè iṣẹ́ fáwọn ènìyàn tátó ẹgbẹ̀rún kan káàkiri ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Ó ní, ilé-iṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ìforúkọ sílẹ̀ àwọn tó ṣetán láti kópa nínú rẹ̀ lósẹ̀ yíí. Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àwọn Bánkì tíjọba bá yàn ni yóò kópa nínú ojúṣe náà,nígbà tíjọba yóò pèsè àyíká tó dára láti mú kójúṣe ọ̀hún kẹ́sẹjárí.

Ọ̀túnba Fáṣaè ní, ìjọba nfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Wema Bank láti ṣèdánilẹ́kọ́ fún àwọn olùkópa tátó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún tọ́jọ́ orí wọn wà láàrín ọdún méjìdínlógún sí àádọ́ta, tíwọn yóò ní ànfàní àti kọ́ onírúurú iṣẹ́ owọ́ bíi ICT, ìmọ̀ lórí iṣẹ́ ọ̀gbìn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Posted in ÌRÒYÌN
Previous
All posts
Next

Write a comment

Ministry of
Information

The official Website, Office of Ekiti State Ministry of Information

Contact Us

+234 8160768195

© 2023 EKSG – Ministry of Information . All Rights Reserved.